AWO FÉLÉ BO'NÚ
Read Count : 135
Category : Poems
Sub Category : N/A
AWO FÉLÉ BO'NÚ. (Soft leather covered the stomach)
Awo félé bonú
Kò jé a rí'kùn asebi
Lágbájá tó ñ bínú
Sùgbón tó ñ feyín kèékèé sí ni
Ñjé ìwó mò pé Inú jìnà j'òrun lō bí?Ōjú larí òré ò dé'nú
Eni a gbójú okùn lé, kò Jo eni āgbā
Awo félé bo'nú kò jé a rí'kùn asebi
Olùfé, e máse rèwèsì, e maa sórā
Bí'kú īlé ò pani, tò'dē kò lee pani
Awo félé bo'nú kò jé a rí'kùn asebi
Sórā fun eeyan ati ohun gbogbo
Ikún ñ bē lóko lóñgé
Máā sórā
Ejò alâwò ewé ñ bē lábé ewé
Òré n pani, máse gb'ara lewon
Ebí le koni, máse gb'árā léwōn
Awo félé bo'nú kò jé a rí'kùn asebi
Aya n pani beeni oko n koni sile
Ina Ife nku beeni okùn Ife n já
© Boluwatife Alabi. O
Comments
- No Comments